Abiọdun Akerele, alaga fẹgbẹ oṣelu BOOT nipinlẹ Ogun, ti sọ pe ninu ẹgbẹ oṣelu ti ko kọyan awọn obinrin kere ni ẹgbẹ wọn, nitori awọn gba pe awọn niyọ aye,wọn ko ṣee fa sẹyin lori ohun gbogbo.
Ọkunrin naa sọrọ yii nibi eto ori redio kan, o sọ pe pataki lobinrin ninu ẹgbẹ, wọn si lawọn ipa to jọju ti wọn ko nidii oṣelu.
O fikun ọrọ ẹ pe ninu awọn oludije ti yoo kopa nibi ibo ọdun to n bọ obinrin wa lara awọn ti wọn fa kalẹ, taa si nireti pe yoo jawe olubori .
Bẹẹ lo si jẹ pe oludije gomina wa, Adekunle Adenuga ko fọrọ wọn ṣere ninu iṣejọba rẹ to ba wọle ibo ọhun
O waa lo akoko naa lati rọ gbogbo awọn obinrin nipinlẹ Ogun lati ṣatilẹyin fẹgbẹ oṣelu BOOT, nitori agbajọwọ la a fi sọya.
O ni ojoojumọ lawọn araalu pariwo pe iṣejọba to n lọ lọwọ yii ko ye wọn, ti wọn si n reti ibo ti yoo waye lọdun to n bọ lati fi gba wọn danu.nitori
Alaga BOOT ṣalaye siwaju pe iyalẹnu lo jẹ foun nitori bawọn araalu ṣe n fojoojumọ darapọ mọ ẹgbẹ wọn, eyi to ni o tumọ si pe ibo ọdun to n bọ yoo yatọ gedegbe si tọdun 2023, to ni awọn araalu ko fi gbogbo ara jade
O ṣalaye siwaju pe,Ẹgbẹ BOOT nipinlẹ Ogun yatọ gedegbe nitori ko si nnkan to n jẹ baba isalẹ, bẹẹ ni ko sẹni to n fowo dari wa.
” Ẹgbẹ wa nii ṣe pẹlu awọn araalu, lati mọ nnkan to n bawọn finra ati ọna abayọ ati pe nnkan to ṣe pataki fun wa ni lati di awọn aye ofo to maa n ṣi ṣilẹ laarin araalu ati ijọba”
Bẹẹ lo sọ pe ki ẹnikẹni ma sọ pe ẹgbẹ bayii nii yoo wọle lọdun to n bọ, nitori ẹgbẹ oṣelu to wa nijọba gan an ko le fi ogun ẹ gbari pe awọn lawọn yoo wọle.
Akerele tun ṣalaye siwaju pe,’ Ni ọpọ ẹgbẹ oṣelu ni oriṣii aawọ wa labẹlẹ ati nita ṣugbọn mo sọ pẹlu idaniloju pe iru nnkan bẹẹ ko si ninu ẹgbẹ ti wa nitori pe agbọye wa daadaa.
“Mo tun fẹẹ ki araalu mọ pe gbogbo awọn oludije wa ni wọn koju oṣuwọn fawọn ipo ti wọn dije fun bẹrẹ lati gomina wa iyẹn ni Adekunle Adenuga atawọn yii.
O ni ẹgbẹ wọn ko fa aṣebajẹ, janduku, ọdaran tabi ẹni to ti kowo ilu jẹ silẹ nitori ọjọ iwaju awọn eeyan gẹgẹ bi orukọ wọn.
Bakan naa lo tun mu da awọn araalu loju pe ko si nnkan to jẹ pe awọn yoo lọ darapọ mọ ẹgbẹ mii ii nigba ti ibo ba ku si dẹdẹ, ayafi tawọn ẹgbẹ oṣelu mii in ba wa sọdọ wọn.
O ni ” Oludije Gomina wa tiẹ maa n sọ pe bi oludije gomina PDP, ba wa sinu ẹgbẹ wọn lati ṣe igbakeji ẹ, a maa tẹwọgba ni.
Alaga wa rọ gbogbo ọmọ ipinlẹ Ogun lati ṣatilẹyin fẹgbẹ BOOT, nitori ẹgbẹ wọn ni, ki wọn si jẹ ki wọn pawọpọ le ijọba to n fara ni araalu danu.

