Breaking

Ko si akọsilẹ buruku nipa Adekunle Adenuga oludije Gomina fẹgbẹ oṣelu BOOT nipinlẹ Ogun-Shobayọ 

 

Alukoro fẹgbẹ oṣelu Because of our Tomorrow, iyẹn Nitori ọjọ iwaju wa, iyẹn BOOT, Ọnarebu Shobayọ Ọlasunkanmi Samuel Adeọla tọpọ mọ si SOSA, ti sọ pe kii ṣe awọn ṣadeede fa oludije Gomina wọn, Adekunle Adenuga kalẹ bi ko ṣe awọn tọpinpin ẹ daadaa tawọn si rii o koju oṣuwọn ati pe ẹni ti yoo fọ ipinlẹ Ogun mọ ni.

 

O sọrọ yii lakooko to n ba oniroyin sọrọ, o sọ pe gẹgẹ bi orukọ ẹgbẹ oṣelu wọn, Nitori ọjọ iwaju wa, bẹẹ lawọn gbọdọ ṣe nnkan ti yoo jẹ ko dara.

 

O ni Adekunle Adenuga ki i ṣe aṣiyan fawọn nitori awọn mọ pe o kaju ẹ.Shobayọ tun sọ pe, “Oludije Gomina wa jẹ akinkanju ati olootọ eeyan, awọn nnkan taa ri ta fi sọ pe wọn le jade dupo ẹgbẹ yii ni pe awa gan an ṣewadii ibi ti wọn ti n bọ, awọn iriri ati imọ ti wọn ti ni o fun wa ni koriya pe iru ẹni to le wa ọkọ ipinlẹ Ogun de ebute rere ni”.

 

Ọkunrin toun naa fẹẹ dije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Ogun fun ẹkun Abẹokuta North tun fikun ọrọ ẹ pe oludije Gomina wọn ki i ṣe onijbiti ẹda tabi huwa ọdaran kan, o ni gbogbo akọsilẹ rẹ lo dara to si wu awọn.

 

Nigba to n sọ ibi ti wọn ba igbaradi wọn de, o sọ pe awọn ti gbinyanju nitori bawọn eeyan ṣe mọ pe o rọrun laisọ idakeji lati ko ẹgbẹ tuntun jọ. Ati lati taa ko to di pe wọn gba a lọwọ onitọhun.

 

O ni awọn ti tan kaakiri gbogbo ijọba ibilẹ nipinlẹ Ogun tawọn naa si ti n tan kalẹ kaakiri. Bẹẹ lo ni titi di akoko yii lawọn fi n ṣe ipolongo ẹgbẹ tawọn araalu si n tẹwọ gba.

 

O tun sọ pe oun ko ri ẹgbẹ APC , PDP, atawọn alatako yooku ro lati dena ẹgbẹ Nitori ọjọ iwaju wa, iyẹn Because of our Tomorrow, BOOT, fun ibo ọdun to n bọ.

 

O sọ pe PDP ati APC ti ṣe ijọba fọpọ ọdun lorileede yii ati nipinlẹ Ogun. Tawọn araalu ti ri ipa ti wọn ko ati nnkan ti wọn le ṣe.

 

O ni, “O ti da wa loju pe ko le si ayipada rere pẹlu oludije yoowu ti wọn ba mu wa, paapaa ọpọ wọn lo ti wa ninu ipo kan ri tẹlẹ.